Proficiency in Yoruba Language
Àwon òrìsà ilè yorùbá
AWON ORISA ILE YORUBA
Lara awon orisa ti o wa nile Yoruba ti won n bo niwonyi: Sango, Ogun, Yemoja, Osun, Orunmila/Ifa, Eegun.
SANGO
Sango je orisa ti o ni agbara lori ina ati aara (fire and thunder).
- Fun idi eyi, aara ni o maa fi n ja.
- Lara awon ohun to feran ni Orogbo, amala pelu gbegiri.
- Awon iyawo re nigba aye re ni: Oya, Osun ati Oba.
- Oun ni won n ki ni:
“Oloju orogbo, eleeke obi
Orisa ti i yo ina lenu….”
- Yoruba tun gbagbo pe o je Alaafin ni Oyo nigba aye re sugbon ibinu pupo ti o ni ati bi o se fe koju awon oloye re meji (Gbonka pelu Timi) sira won da ijoba re ru.
- O binu pokunso nigba ti won le e kuro ni Oyo tan.
- Sango lo maa n bere oruko awon omo to ti ile ti won ti n sin orisa Sango wa b.a: Sangotayo, Sangodare abbl.
- Lara awon oloye Sango ni Babamogba, Iyamogba, Adosu ati Elegun.
- Awon ohun irubo si Sango ni Orogbo, amala, obe gbegiri eran agbo, akuko, obi, ataare, ewa ososo.
Eewo: Awon onisango ko gbodo mu taba/siga, je ewa sese, je eku ago, je eran esuo, gbe ina ru.
ORISA OGUN
- Yoruba gba pe alagbara orisa to ni agbara lori gbogbo ohun to ba je mo irin ni.
- Oun ni won maa n ki pe:
- Ogun Onire
A jeun oluwonran
Koriko odo tii ru winniwinni
“Lojo to n ti ori oke bo
Aso ina lo fi bora, ewu eje lo wo sorun..”
- Mariwo ni aso Ogun
- Awon olode, alagbede pelu awon to n lo ohun elo irin fun ise won lo maa n sin/boo gun.
- Aja ni won fi n bo Ogun. Awon ohun ti won tun fi n bo o leyin aja ni: ewa eyan, igbin, agbo, eyele, iyan, orogbo, obi, eko tutu, ekuru, iyan.
- A ko gbodo sufee ninu agbede, won ki i pa ile aro (agbede), alagbede ko gbodo je efo egunmo, awon olusin ogun ko gbodo fi bura eke, egungun ko gbodo wo ile agbede, a ko gbodo so ninu agbede bi a ba jokoo lori Ogun.
- Oruko Ogun lo saaba maa n bere oruko awon omo ti idile won n sin Ogun b.a: Ogunyemi, Ogunjimi abbl.
- Oloye Ogun ni Eleede
OBATALA
- Obatala naa ni won n pe ni Orisa nla
- Oun lo n se oluranlowo fun Olodumare ninu ise iseda – oun lo n se oju, imu, enu, eti ati awon eya ara yooku leyin ti Ọlọrun ba ti da ara tan.
- Idi niyi ti won fi n pe e ni Alamo rere.
- Aso funfun ni awon olusin re maa n wo.
- Awon ohun to feran ti won fi maa n rubo si i ni: iyan funfun, obe osiki (ti ko lepo), eran igbin, obi ifin oloju merin, omi ajipon, agbebo adie funfun, eyele funfun.
- Awon oloye: Aboosa, Aworo/Abore
- Eewo: Won ko gbodo fi iyan isu igangan, obe elepo pupa ati eran nama rubo si i, O tun koriira emu (awon olusin re naa ko gbodo mu un) iyo, epo bee ni ko fe iro.
ORO
- Orisa ti won fi n wa alaafia si ilu ni orisa oro ti nnkan ba fe dojuru.
- Yoruba a tun maa fi oro gbe eni to ba n se aida ni ilu tabi fi oro le eni to ba fe buru ju niluu jade.
- Okunrin nikan ni o maa n kopa ninu awon oro.
- Yato si ki a se etutu si ilu, awon oloro ni o maa n sin oku alaboyun to ba ku sinu igbo oro.
- Aiwo ni igbo oro je fun obinrin tabi ogberi (eni ti ko ba si ninu awon oloro)
- Olori awon oloro tabi oloye awon Oloro ni Ajana.
Awon ohun irubo: obuko, akuko adie, elede, amala (oka), eko, iyan, ewa, asaro.
Eewo: Obinrin ko gbodo wo oro tabi kopa ninu awo oro, won ko gbodo fi orogbo bo oro, a ki i ri ajeku oro. Eni ba fi oro bura eke a wu ku.
ORUNMILA/IFA
- Awon babalawo lo n sin Ifa tabi Orunmila.
- Orunmila ni Yoruba gbagbo gege bi orisa elerii ipin.
- O ni agbara lati mo ohun ti yoo sele lojo iwaju.
- Awon orisa yooku pelu eeyan maa n lo sodo re lati se iwadii ohun to ba ruju fun won.
- Awon Oloye esin Ifa ni: Oluawo, Araba.
- Awon ohun irubo si Orunmila ni: obi, ewure, eku, adie, eja gbigbe pelu awon ohun ti ifa ba beere bi ohun irubo.
- Eewo: awo ko gbodo seke, gba iyawo ara won dale ara won.
ESU
- Okan lara awon ibo (orisa akunlebo) ile Yoruba ni Esu.
- Itan kan so pe Ijelu-Ekiti ni ilu Esu.
- Awon oruko miiran ti Yoruba n pe Esu ni: Elegbara, Latopa, Laaroye, Onile-orita, Ajongbolo, Labureke, Akobi Ogun.
- Esu inu esin abalaye yato si esin igbalode (Satani) – Ibi nikan ko ni Esu esin abalaye n se. idi niyi ti won fi n pe e ni Aseburuku-se-rere.
- Ore Orunmila ni.
- Oun ni olopaa laarin Ọlọrun, eeyan ati awon orisa to ku.
- Ere tabi okuta yangi ni ami idamo to maa n wa ni ojubo re.
- Ere Esu maa n gbe kondo nla lowo.
- Awon elomiiran n bo Esu ni orita tabi ni oju ita ile.
- Awon ohun irubo si Esu: Epo pupa, obuko, elede, aja, akuko, igbin, eko, obi, iyan, eku, eye, ewa pelu orisirisi ohun ti enu maa n je ni won fi n bo Esu.
- Awon to n sin Esu maa n so omo won loruko to bere pelu Esu: Esubunmi, Esufunke, abbl.
- Eewo: Orisa to koriira adi ni. Won ko gbodo fun un ni adi (adin)/yanko ati omi gbigbona, won ko gbodo fi igbin bo Esu.
Oya
- Orisa omi/odo ni Oya je.
- Okan lara awon iyawo Sango ni Oya nigba aye re.
- Oun ni Yoruba gbagbo pe o ni agbara afefe (ategun) lowo ti o ma fi n ja nigba ti Sango oko re a maa fi aara ja.
- Oruko awon olusin Oya a maa bere pelu ‘Oya’ bi apeere Oyabunmi, Oyafunke, Oyadiran, abbl.
- Awon ohun ti won fi n bo Oya ni: ewure, amala, adie, elede, pepeye, eko, egbo, obi, orogbo.
- Okan lara awon ami idamo awon olusin Oya ni aso funfun ti won maa n wo.
- Eewo awon oloya ni pe won ko gbodo je eran agbo, won ko gbodo sin in, won ko gbodo je eran aja.